1.O SI ṣe li akokò na, ni Judah sọkalẹ lọ kuro lọdọ awọn arakunrin rẹ̀, o si yà sọdọ ara Adullamu kan, orukọ ẹniti ijẹ́ Hira.
2.Judah si ri ọmọbinrin ara Kenaani kan nibẹ̀, orukọ ẹniti ijẹ́ Ṣua; o si mú u, o si wọle tọ̀ ọ.
3.O si yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si sọ orukọ rẹ̀ ni Eri.
4.O si tun yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si sọ orukọ rẹ̀ ni Onani.
5.O si tun yún, o si bí ọmọkunrin kan; o si sọ orukọ rẹ̀ ni Ṣela: o wà ni Kesibu, nigbati o bí i.
6.Judah si fẹ́ aya fun Eri akọ́bi rẹ̀, orukọ ẹniti ijẹ́ Tamari.
7.Eri akọ́bi Judah si ṣe enia buburu li oju OLUWA; OLUWA si pa a.
8.Judah si wi fun Onani pe, Wọle tọ̀ aya arakunrin rẹ lọ, ki o si ṣú u li opó, ki o si bimọ si ipò arakunrin rẹ.
9.Onani si mọ̀ pe, irú-ọmọ ki yio ṣe tirẹ̀; o si ṣe bi o ti wọle tọ̀ aya arakunrin rẹ̀ lọ, o si dà a silẹ, ki o má ba fi irú-ọmọ fun arakunrin rẹ̀.
10.Ohun ti o si ṣe buru loju OLUWA, nitori na li OLUWA pa a pẹlu.
11.Nigbana ni Judah wi fun Tamari aya ọmọ rẹ̀ pe, Joko li opó ni ile baba rẹ, titi Ṣela ọmọ mi o fi dàgba: nitori o wipe, Ki on má ba kú pẹlu, bi awọn arakunrin rẹ̀. Tamari si lọ, o si joko ni ile baba rẹ̀.
12.Nigbati ọjọ́ si npẹ́, ọmọbinrin Ṣua, aya Juda kú; Judah si gbipẹ̀, o si tọ̀ awọn olurẹrun agutan rẹ̀, lọ si Timnati, on ati Hira ọ̀rẹ́ rẹ̀, ara Adullamu.
13.A si wi fun Tamari pe, Kiyesi i, baba ọkọ rẹ lọ si Timnati lati rẹrun agutan rẹ̀.
14.O si bọ́ aṣọ opó rẹ̀ kuro li ara rẹ̀, o si fi iboju bò ara rẹ̀, o si roṣọ, o si joko li ẹnubode Enaimu, ti o wà li ọ̀na Timnati; nitoriti o ri pe Ṣela dàgba, a kò si fi on fun u li aya.
15.Nigbati Judah ri i, o fi i pè panṣaga; nitori o boju rẹ̀.
16.O si yà tọ̀ ọ li ẹba ọ̀na, o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, wá na, jẹ ki emi ki o wọle tọ̀ ọ; (on kò sa mọ̀ pe aya ọmọ on ni iṣe.) On si wipe Kini iwọ o fi fun mi, ki iwọ ki o le wọle tọ̀ mi?
17.O si wipe, emi o rán ọmọ ewurẹ kan si ọ lati inu agbo wá. On si wipe, iwọ ki o fi ògo fun mi titi iwọ o fi rán a wá?
18.O si bi i pe, Ògo kili emi o fi fun ọ? on si wipe, Èdidi rẹ, ati okùn rẹ, ati ọpá rẹ ti o wà li ọwọ́ rẹ; o si fi wọn fun u, o si wọle tọ̀ ọ lọ, on si ti ipa ọdọ rẹ̀ yún.
19.On si dide, o ba tirẹ̀ lọ, o si bọ́ iboju rẹ̀ lelẹ kuro lara rẹ̀, o si mú aṣọ opó rẹ̀ ró.
20.Judah si rán ọmọ ewurẹ na lati ọwọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, ara Adullamu na lọ, lati gbà ògo nì wá lọwọ obinrin na: ṣugbọn on kò ri i.
21.Nigbana li o bère lọwọ awọn ọkunrin ibẹ̀ na pe, Nibo ni panṣaga nì ngbé, ti o wà ni Enaimu li ẹba ọ̀na? Nwọn si wipe, Panṣaga kan kò sí nihin.
22.O si pada tọ̀ Judah lọ, o si wipe, Emi kò ri i; ati pẹlu awọn ọkunrin ara ibẹ̀ na wipe, Kò sí panṣaga kan nibẹ̀.
23.Judah si wipe, Jẹ ki o ma mú u fun ara rẹ̀, ki oju ki o má tì wa: kiyesi i, emi rán ọmọ ewurẹ yi, iwọ kò si ri i.
24.O si ṣe niwọ̀n oṣù mẹta lẹhin rẹ̀, ni a wi fun Judah pe, Tamari aya ọmọ rẹ ṣe àgbere; si kiyesi i pẹlu, o fi àgbere loyun. Judah si wipe, Mú u jade wá, ki a si dána sun u.
25.Nigbati a si mú u jade, o ranṣẹ si baba ọkọ rẹ̀ pe, ọkunrin ti o ní nkan wọnyi li emi yún fun: o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, mọ̀ wọn, ti tani nkan wọnyi, èdidi, ati okùn, ati ọpá.
26.Judah si jẹwọ, o si wipe, O ṣe olododo jù mi lọ; nitori ti emi kò fi i fun Ṣela ọmọ mi. On kò si mọ̀ ọ mọ́ lai.
27.O si ṣe li akokò ti o nrọbí, si kiyesi i, ìbejì wà ni inu rẹ̀.
28.O si ṣe nigbati o nrọbí, ti ọkan yọ ọwọ́ jade: iyãgba si mú okùn ododó o so mọ́ ọ li ọwọ́, o wipe, Eyi li o kọ jade.
29.O si ṣe, bi o ti fà ọwọ́ rẹ̀ pada, si kiyesi i, aburo rẹ̀ jade: o si wipe, Ẽṣe ti iwọ fi yà? yiyà yi wà li ara rẹ, nitori na li a ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Peresi:
30.Nikẹhin li arakunrin rẹ̀ jade, ti o li okùn ododó li ọwọ́ rẹ̀: a si sọ orukọ rẹ̀ ni Sera.