1.
OLUWA da Jobu lohùn si i pẹlu, o si wipe,
2.
Ẹniti mba Olodumare jà, yio ha kọ́ ọ li ẹkọ́? ẹniti mba Ọlọrun wi, jẹ ki o dahùn!
3.
Nigbana ni Jobu da Oluwa lohùn, o si wipe:
4.
Kiyesi i, ẹgbin li emi; ohùn kili emi o da? emi o fi ọwọ mi le ẹnu mi.
5.
Ẹ̃kan ni mo sọ̀rọ̀, ṣugbọn emi kì yio si tun sọ mọ, lẹ̃meji ni, emi kò si le iṣe e mọ́.
6.
Nigbana ni OLUWA da Jobu lohùn lati inu ìji ajayika wá o si wipe:
7.
Di àmure giri li ẹgbẹ rẹ bi ọkunrin, emi o bi ọ lere, ki iwọ ki o si kọ́ mi li ẹkọ́.
8.
Iwọ ha fẹ imu idajọ mi di asan? iwọ o si da mi lẹbi, ki iwọ ki o le iṣe olododo?
9.
Iwọ ni apá bi Ọlọrun, tabi iwọ le ifi ohùn san ãrá bi on?
10.
Fi ọlanla ati ọla-itayọ ṣe ara rẹ li ọṣọ, ki o si fi ogo ati ẹwa ọṣọ bò ara rẹ li aṣọ.
11.
Mu irunu ibinu rẹ jade, kiyesi gbogbo ìwa igberaga, ki o si rẹ̀ ẹ silẹ.
12.
Wò gbogbo ìwa igberaga, ki o si rẹ̀ ẹ silẹ, ki o si tẹ enia buburu mọlẹ ni ipo wọn.
13.
Fi wọn sin pọ̀ ninu erupẹ, ki o si di oju wọn ni ikọkọ.
14.
Nigbana li emi o yìn ọ pe, ọwọ ọ̀tun ara rẹ le igba ọ la.
15.
Njẹ nisisiyi kiyesi Behemotu ti mo da pẹlu rẹ, on a ma jẹ koriko bi ọ̀da-malu.
16.
Wò o nisisiyi, agbara rẹ̀ wà li ẹgbẹ́ rẹ̀, ati ipa rẹ̀ ninu iṣan ikún rẹ̀.
17.
On a ma jù ìru rẹ̀ bi igi kedari, iṣan itan rẹ̀ dijọ pọ̀.
18.
Egungun rẹ̀ ni ogusọ idẹ, egungun rẹ̀ dabi ọpa irin.
19.
On ni olu nipa ọ̀na Ọlọrun; ẹniti o da a o fi idà rẹ̀ le e lọwọ.
20.
Nitõtọ oke nlanla ni imu ohun jijẹ fun u wá, nibiti gbogbo ẹranko igbẹ ima ṣire.
21.
O dubulẹ labẹ igi Lotosi, ninu ifefe bibò ati ẹrẹ.
22.
Igi Lotosi ṣiji wọn bò o, igi arọrọ odò yi i kakiri.
23.
Kiyesi i, odò nla ṣan jọjọ, on kò salọ, o wà lailewu bi o ba ṣe odò Jordani ti ṣan lọ si ẹnu rẹ̀.
24.
Ẹnikan ha le imu u li oju rẹ̀ tabi a ma fi ọkọ gun imú rẹ̀?