1.
Ẹ ma yìn Oluwa. Emi o ma yìn Oluwa tinutinu mi, ninu ijọ awọn ẹni diduro-ṣinṣin, ati ni ijọ enia.
2.
Iṣẹ Oluwa tobi, iwa-kiri ni fun gbogbo awọn ti o ni ifẹ rẹ̀ ninu.
3.
Iṣe rẹ̀ li ọlá on ogo, ododo rẹ̀ si duro lailai.
4.
O ṣe iṣẹ iyanu rẹ̀ ni iranti: olore-ọfẹ́ li Oluwa o si kún fun ãnu.
5.
O ti fi onjẹ fun awọn ti o bẹ̀ru rẹ̀: yio ranti majẹmu rẹ̀ lailai.
6.
O ti fi iṣẹ agbara rẹ̀ hàn awọn enia rẹ̀, ki o le fun wọn ni ilẹ-ini awọn keferi.
7.
Otitọ ati idajọ ni iṣẹ ọwọ rẹ̀; gbogbo ofin rẹ̀ li o daniloju.
8.
Nwọn duro lai ati lailai, ninu otitọ ati iduro-ṣinṣin li a ṣe wọn.
9.
O rán idande si awọn enia rẹ̀: o ti paṣẹ majẹmu rẹ̀ lailai: mimọ́ ati ọ̀wọ li orukọ rẹ̀.
10.
Ibẹru Oluwa ni ipilẹṣẹ ọgbọ́n: oye rere ni gbogbo awọn ti npa ofin rẹ̀ mọ́ ni: iyìn rẹ̀ duro lailai.