1.
Ẹ ma yìn Oluwa! Ẹ ma yìn, ẹnyin iranṣẹ Oluwa, ẹ ma yìn orukọ Oluwa.
2.
Ibukún li orukọ Oluwa lati isisiyi lọ ati si i lailai.
3.
Lati ila-õrun titi o fi de ìwọ rẹ̀ orukọ Oluwa ni ki a yìn.
4.
Oluwa ga lori gbogbo orilẹ-ède, ogo rẹ̀ si wà lori ọrun.
5.
Tali o dabi Oluwa Ọlọrun wa, ti o ngbe ibi giga.
6.
Ẹniti o rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ lati wò ohun ti o wà li ọrun ati li aiye!
7.
O gbé talaka soke lati inu erupẹ wá, o si gbé olupọnju soke lati ori àtan wá;
8.
Ki o le mu u joko pẹlu awọn ọmọ-alade, ani pẹlu awọn ọmọ-alade awọn enia rẹ̀.
9.
O mu àgan obinrin gbe inu ile, lati ma ṣe oninu-didùn iya awọn ọmọ. Ẹ ma yìn Oluwa!