1.
NIGBATI Israeli jade kuro ni Egipti, ti ara-ile Jakobu kuro ninu àjeji ède enia;
2.
Juda di ibi mimọ́ rẹ̀, Israeli di ijọba rẹ̀.
3.
Okun ri i, o si sá: Jordani pada sẹhin.
4.
Awọn òke nla nfò bi àgbo, ati awọn òke kekèke bi ọdọ-agutan.
5.
Kili o ṣe ọ, iwọ okun, ti iwọ fi sá? iwọ Jordani ti iwọ fi pada sẹhin?
6.
Ẹnyin òke nla, ti ẹ fi nfò bi àgbo; ati ẹnyin òke kekèke bi ọdọ-agutan?
7.
Warìri, iwọ ilẹ, niwaju Oluwa, niwaju Ọlọrun Jakobu.
8.
Ẹniti o sọ apata di adagun omi, ati okuta-ibọn di orisun omi.