1.
KÌ iṣe fun wa, Oluwa, kì iṣe fun wa, bikoṣe orukọ rẹ li a fi ogo fun nitori ãnu rẹ, ati nitori otitọ rẹ.
2.
Nitori kili awọn keferi yio ṣe wipe, Nibo li Ọlọrun wọn wà nisisiyi?
3.
Ṣugbọn Ọlọrun wa mbẹ li ọrun: o nṣe ohun-kohun ti o wù u.
4.
Fadaka ati wura li ere wọn, iṣẹ ọwọ enia.
5.
Nwọn li ẹnu, ṣugbọn nwọn kò sọ̀rọ: nwọn li oju, ṣugbọn nwọn kò riran.
6.
Nwọn li eti, ṣugbọn nwọn kò gbọran: nwọn ni imu, ṣugbọn nwọn kò gbõrun.
7.
Nwọn li ọwọ, ṣugbọn nwọn kò lò o: nwọn li ẹsẹ, ṣugbọn nwọn kò rìn: bẹ̃ni nwọn kò sọ̀rọ lati ọfun wọn jade.
8.
Awọn ti nṣe wọn dabi wọn; bẹ̃li olukuluku ẹniti o gbẹkẹle wọn.
9.
Israeli, iwọ gbẹkẹle Oluwa: on ni iranlọwọ wọn ati asà wọn.
10.
Ara-ile Aaroni, gbẹkẹle Oluwa, on ni iranlọwọ wọn ati asà wọn.
11.
Ẹnyin ti o bẹ̀ru Oluwa, gbẹkẹle Oluwa: on ni iranlọwọ wọn ati asà wọn.
12.
Oluwa ti nṣe iranti wa: yio bùsi i fun wa: yio bùsi i fun ara-ile Israeli; yio bùsi i fun ara-ile Aaroni.
13.
Yio bùsi i fun awọn ti o bẹ̀ru Oluwa, ati ewe ati àgba.
14.
Oluwa yio mu nyin bisi i siwaju ati siwaju, ẹnyin ati awọn ọmọ nyin.
15.
Ẹnyin li ẹni-ibukún Oluwa, ti o da ọrun on aiye.
16.
Ọrun ani ọrun ni ti Oluwa; ṣugbọn aiye li o fi fun awọn ọmọ enia.
17.
Okú kò yìn Oluwa, ati gbogbo awọn ti o sọkalẹ lọ sinu idakẹ.
18.
Ṣugbọn awa o ma fi ibukún fun Oluwa, lati igba yi lọ ati si i lailai. Ẹ yìn Oluwa.