1.
EMI fẹ Oluwa nitori ti o gbọ́ ohùn mi ati ẹ̀bẹ mi.
2.
Nitori ti o dẹ eti rẹ̀ si mi, nitorina li emi o ma kepè e niwọn ọjọ mi.
3.
Ikẹkùn ikú yi mi ka, ati irora isà-òkú di mi mu; mo ri iyọnu ati ikãnu.
4.
Nigbana ni mo kepè orukọ Oluwa; Oluwa, emi bẹ̀ ọ, gbà ọkàn mi.
5.
Olore-ọfẹ li Oluwa, ati olododo; nitõtọ, alãnu li Ọlọrun wa.
6.
Oluwa pa awọn alaimọ̀kan mọ́: a rẹ̀ mi silẹ tan, o si ràn mi lọwọ.
7.
Pada si ibi isimi rẹ, iwọ ọkàn mi; nitori ti Oluwa ṣe é lọ́pọlọpọ fun ọ.
8.
Nitori ti iwọ gbà ọkàn mi lọwọ ikú, oju mi lọwọ omije, ati ẹsẹ mi lọwọ iṣubu.
9.
Emi o ma rìn niwaju Oluwa ni ilẹ alãye.
10.
Emi gbagbọ́, nitorina li emi ṣe sọ: mo ri ipọnju gidigidi.
11.
Mo wi ni iyara mi pe: Eke ni gbogbo enia.
12.
Kili emi o san fun Oluwa nitori gbogbo ore rẹ̀ si mi?
13.
Emi o mu ago igbala, emi o si ma kepè orukọ Oluwa.
14.
Emi o san ileri ifẹ mi fun Oluwa, nitõtọ li oju gbogbo awọn enia rẹ̀.
15.
Iyebiye ni ikú awọn ayanfẹ rẹ̀ li oju Oluwa.
16.
Oluwa nitõtọ iranṣẹ rẹ li emi; iranṣẹ rẹ̀ li emi, ati ọmọ iranṣẹ-birin rẹ: iwọ ti tú ìde mi.
17.
Emi o ru ẹbọ ọpẹ si ọ, emi o ma ke pè orukọ Oluwa.
18.
Emi o san ileri ifẹ mi fun Oluwa, nitõtọ li oju gbogbo awọn enia rẹ̀.
19.
Ninu àgbala ile Oluwa, li arin rẹ, iwọ Jerusalemu. Ẹ yìn Oluwa.