1.
Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa; nitoriti o ṣeun, nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai.
2.
Jẹ ki Israeli ki o wi nisisiyi pe, ãnu rẹ̀ duro lailai.
3.
Jẹ ki ara-ile Aaroni ki o wi nisisiyi pe, ãnu rẹ̀ duro lailai.
4.
Jẹ ki awọn ti o bẹ̀ru Oluwa ki o wi nisisiyi pe, ãnu rẹ̀ duro lailai.
5.
Mo kepè Oluwa ninu ipọnju: Oluwa si da mi lohùn ni ibi àye nla.
6.
Oluwa mbẹ fun mi, emi kì yio bẹ̀ru; kili enia le ṣe si mi?
7.
Oluwa mbẹ fun mi pẹlu awọn ti nràn mi lọwọ: nitorina li emi o ṣe ri ifẹ mi lori awọn ti o korira mi.
8.
O ya lati gbẹkẹle Oluwa, jù ati gbẹkẹle enia lọ.
9.
O ya lati gbẹkẹle Oluwa, jù ati gbẹkẹle awọn ọmọ-alade lọ.
10.
Gbogbo awọn orilẹ-ède yi mi ka kiri, ṣugbọn li orukọ Oluwa emi o pa wọn run.
11.
Nwọn yi mi ka kiri; nitõtọ, nwọn yi mi ka kiri, ṣugbọn li orukọ Oluwa emi o pa wọn run.
12.
Nwọn yi mi ka kiri bi oyin; a si pa wọn bi iná ẹgún: li orukọ Oluwa emi o sa pa wọn run.
13.
Iwọ tì mi gidigidi ki emi ki o le ṣubu; ṣugbọn Oluwa ràn mi lọwọ.
14.
Oluwa li agbara ati orin mi, o si di igbala mi.
15.
Ìró ayọ̀ ati ti ìṣẹ́gun mbẹ ninu agọ awọn olododo; ọwọ ọtún Oluwa li a gbega: ọwọ ọtún Oluwa nṣe agbara.
16.
Ọwọ ọtún Oluwa li a gbega: ọwọ ọtún Oluwa nṣe agbara.
17.
Emi kì yio kú, bikoṣe yiyè, ki emi ki o si ma rohin iṣẹ Oluwa.
18.
Oluwa nà mi gidigidi: ṣugbọn kò fi mi fun ikú.
19.
Ṣi ilẹkun ẹnu-ọ̀na ododo silẹ fun mi: emi o ba ibẹ wọle, emi o ma yìn Oluwa.
20.
Eyi li ẹnu-ọ̀na Oluwa, ti awọn olododo yio ba wọle.
21.
Emi o yìn ọ: nitori ti iwọ gbohùn mi, iwọ si di igbala mi.
22.
Okuta ti awọn ọ̀mọle kọ̀ silẹ li o di pataki igun ile.
23.
Lati ọdọ Oluwa li eyi: o ṣe iyanu li oju wa.
24.
Eyi li ọjọ ti Oluwa da: awa o ma yọ̀, inu wa yio si ma dùn ninu rẹ̀.
25.
Ṣe igbala nisisiyi, emi mbẹ ọ, Oluwa: Oluwa emi bẹ ọ, rán alafia.
26.
Olubukún li ẹniti o mbọ̀ wá li orukọ Oluwa: awa ti fi ibukún fun ọ lati ile Oluwa wá.
27.
Ọlọrun li Oluwa, ti o ti fi imọlẹ hàn fun wa: ẹ fi okùn di ẹbọ na mọ́ iwo pẹpẹ na.
28.
Iwọ li Ọlọrun mi, emi o si ma yìn ọ, iwọ li Ọlọrun mi, emi o mã gbé ọ ga.
29.
Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa; nitori ti o ṣeun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.