1.
NINU ipọnju mi emi kepè Oluwa, o si da mi lohùn.
2.
Oluwa, gbà ọkàn mi, lọwọ ète eke, ati lọwọ ahọn ẹ̀tan?
3.
Kini ki a fi fun ọ? tabi kini ki a ṣe si ọ, ahọn ẹ̀tan.
4.
Ọfà mimu alagbara, ti on ti ẹyin-iná igi juniperi!
5.
Egbe ni fun mi, ti mo ṣe atipo ni Meṣeki, ti mo joko ninu agọ Kedari!
6.
O ti pẹ ti ọkàn mi ti ba ẹniti o korira alafia gbe.
7.
Alafia ni mo fẹ: ṣugbọn nigbati mo ba sọ̀rọ, ija ni ti wọn.