1.
EMI o gbé oju mi si ori oke wọnnì, nibo ni iranlọwọ mi yio ti nwa?
2.
Iranlọwọ mi yio ti ọwọ Oluwa wá, ti o da ọrun on aiye.
3.
On kì yio jẹ́ ki ẹsẹ rẹ ki o yẹ̀; ẹniti npa ọ mọ́ kì yio tõgbe.
4.
Kiyesi i, ẹniti npa Israeli mọ́, kì itõgbe, bẹ̃ni kì isùn.
5.
Oluwa li olupamọ́ rẹ: Oluwa li ojiji rẹ li ọwọ ọ̀tún rẹ.
6.
Orùn kì yio pa ọ nigba ọsan, tabi oṣupa nigba oru.
7.
Oluwa yio pa ọ mọ́ kuro ninu ibi gbogbo: yio pa ọkàn rẹ mọ́.
8.
Oluwa yio pa alọ ati àbọ rẹ mọ́ lati igba yi lọ, ati titi lailai.