1.
INU mi dùn nigbati nwọn wi fun mi pe, Ẹ jẹ ki a lọ si ile Oluwa.
2.
Ẹsẹ wa yio duro ni ẹnu-bode rẹ, iwọ Jerusalemu.
3.
Jerusalemu, iwọ ti a kọ́ bi ilu ti o fi ara mọra pọ̀ ṣọkan.
4.
Nibiti awọn ẹ̀ya ima gòke lọ, awọn ẹ̀ya Oluwa, ẹri fun Israeli, lati ma dupẹ fun orukọ Oluwa.
5.
Nitori ibẹ li a gbé itẹ́ idajọ kalẹ, awọn itẹ́ ile Dafidi.
6.
Gbadura fun alafia Jerusalemu: awọn ti o fẹ ọ yio ṣe rere.
7.
Ki alafia ki o wà ninu odi rẹ, ati ire ninu ãfin rẹ.
8.
Nitori awọn arakunrin ati awọn ẹgbẹ mi, emi o wi nisisiyi pe, Ki alafia ki o wà ninu rẹ!
9.
Nitori ile Oluwa Ọlọrun wa, emi o ma wá ire rẹ.