1.
Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa: nitoriti o ṣeun; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
2.
Ẹ fi ọpẹ fun Ọlọrun awọn ọlọrun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
3.
Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa awọn oluwa: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
4.
Fun on nikan ti nṣe iṣẹ iyanu nla: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
5.
Fun ẹniti o fi ọgbọ́n da ọrun: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
6.
Fun ẹniti o tẹ́ ilẹ lori omi: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
7.
Fun ẹniti o dá awọn imọlẹ nla: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
8.
Õrùn lati jọba ọsan: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai:
9.
Oṣupa ati irawọ lati jọba oru: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
10.
Fun ẹniti o kọlù Egipti lara awọn akọbi wọn: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
11.
O si mu Israeli jade kuro lãrin wọn: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai:
12.
Pẹlu ọwọ agbara, ati apa ninà: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
13.
Fun ẹniti o pin Okun pupa ni ìya: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai:
14.
O si mu Israeli kọja lọ larin rẹ̀: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
15.
Ṣugbọn o bi Farao ati ogun rẹ̀ ṣubu ninu Okun pupa: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
16.
Fun ẹniti o sin awọn enia rẹ̀ la aginju ja: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
17.
Fun ẹniti o kọlù awọn ọba nla: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
18.
O si pa awọn ọba olokiki: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
19.
Sihoni, ọba awọn ara Amori: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
20.
Ati Ogu, ọba Baṣani: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
21.
O si fi ilẹ wọn funni ni ini, nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
22.
Ini fun Israeli, iranṣẹ rẹ̀; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
23.
Ẹniti o ranti wa ni ìwa irẹlẹ wa; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
24.
O si dá wa ni ìde lọwọ awọn ọta wa; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.
25.
Ẹniti o nfi onjẹ fun ẹda gbogbo: nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai;
26.
Ẹ fi ọpẹ fun Ọlọrun ọrun; nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.