1.
Ẹ fi iyìn fun Oluwa, Ẹ fi iyìn fun Oluwa lati ọrun wá; ẹ fi iyìn fun u ni ibi giga.
2.
Ẹ fi iyìn fun u, gbogbo ẹnyin angeli rẹ̀; ẹ fi iyìn fun u, gbogbo ẹnyin ọmọ-ogun rẹ̀.
3.
Ẹ fi iyìn fun u, õrun ati oṣupa; ẹ fi iyìn fun u, gbogbo ẹnyin irawọ imọlẹ.
4.
Ẹ fi iyìn fun u, ẹnyin ọrun awọn ọrun, ati ẹnyin omi ti mbẹ loke ọrun.
5.
Jẹ ki nwọn ki o ma yìn orukọ Oluwa; nitori ti on paṣẹ, a si da wọn.
6.
O si fi idi wọn mulẹ lai ati lailai; o si ti ṣe ilana kan ti kì yio kọja.
7.
Ẹ yìn Oluwa lati aiye wá, ẹnyin erinmi, ati gbogbo ibu-omi;
8.
Iná ati yinyin òjo-didì ati ikũku; ìji mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ;
9.
Ẹnyin òke nla, ati gbogbo òke kekere; igi eleso, ati gbogbo igi Kedari;
10.
Ẹranko, ati gbogbo ẹran-ọ̀sin; ohun ti nrakò, ati ẹiyẹ́ ti nfò;
11.
Awọn ọba aiye, ati gbogbo enia; ọmọ-alade, ati gbogbo onidajọ aiye;
12.
Awọn ọdọmọkunrin ati awọn wundia, awọn arugbo enia ati awọn ọmọde;
13.
Ki nwọn ki o ma yìn orukọ Oluwa; nitori orukọ rẹ̀ nikan li o li ọlá; ogo rẹ̀ bori aiye on ọrun.
14.
O si gbé iwo kan soke fun awọn enia rẹ̀, iyìn fun gbogbo enia mimọ́ rẹ̀; ani awọn ọmọ Israeli, awọn enia ti o sunmọ ọdọ rẹ̀. Ẹ fi iyìn fun Oluwa.