1.
KI Oluwa ki o gbohùn rẹ li ọjọ ipọnju; orukọ Ọlọrun Jakobu ki o dàbobo ọ.
2.
Ki o rán iranlọwọ si ọ lati ibi-mimọ́ wá, ki o si tì ọ lẹhin lati Sioni wá.
3.
Ki o ranti ẹbọ-ọrẹ rẹ gbogbo, ki o si gbà ẹbọ sisun rẹ.
4.
Ki o fi fun ọ gẹgẹ bi ti inu rẹ, ki o si mu gbogbo ìmọ rẹ ṣẹ.
5.
Awa o ma kọrin ayọ̀ igbala rẹ, ati li orukọ Ọlọrun wa li awa o fi ọpágun wa de ilẹ; ki Oluwa ki o mu gbogbo ibère rẹ ṣẹ.
6.
Nigbayi ni mo to mọ̀ pe Oluwa gbà Ẹni-ororo rẹ̀ là; yio gbọ́ ọ lati ọrun mimọ́ rẹ̀ wá nipa agbara igbala ọwọ ọ̀tun rẹ̀.
7.
Awọn ẹlomiran gbẹkẹle kẹkẹ́, awọn ẹlomiran le ẹṣin; ṣugbọn awa o ranti orukọ Oluwa Ọlọrun wa.
8.
Nwọn wolẹ, nwọn si ṣubu: ṣugbọn awa dide awa si duro ṣinṣin.
9.
Gbani, Oluwa, ki Ọba ki o gbọ nigbati awa ba nkigbe pe e.