1.
Ẹ FI fun Oluwa, ẹnyin ọmọ awọn alagbara, ẹ fi ogo ati agbara fun Oluwa.
2.
Ẹ fi ogo fun Oluwa, ti o yẹ fun orukọ rẹ̀; ẹ ma sìn Oluwa ninu ẹwà ìwa-mimọ́.
3.
Ohùn Oluwa mbẹ lori omi pupọ̀: Ọlọrun ogo nsán ãrá: Oluwa mbẹ lori omi pupọ̀.
4.
Ohùn Oluwa li agbara; ohùn Oluwa ni ọlánla.
5.
Ohùn Oluwa nfà igi kedari ya; lõtọ, Oluwa nfà igi kedari Lebanoni ya.
6.
O mu wọn fò pẹlu bi ọmọ-malu; Lebanoni on Sirioni bi ọmọ agbanrere.
7.
Ohùn Oluwa nyà ọwọ iná,
8.
Ohùn Oluwa nmì aginju; Oluwa nmì aginju Kadeṣi.
9.
Ohùn Oluwa li o nmu abo agbọnrin bi, o si fi igbo didi hàn: ati ninu tempili rẹ̀ li olukuluku nsọ̀rọ ogo rẹ̀.
10.
Oluwa joko lori iṣan-omi; nitõtọ, Oluwa joko bi Ọba lailai.
11.
Oluwa yio fi agbara fun awọn enia rẹ̀; Oluwa yio fi alafia busi i fun awọn enia rẹ̀.