1.
ẸNI-NLA ni Oluwa, ti ã yìn pupọpupọ, ni ilu Ọlọrun wa, li oke ìwa-mimọ́ rẹ̀.
2.
Didara ni ipò itẹdo, ayọ̀ gbogbo aiye li òke Sioni, ni iha ariwa, ilu Ọba nla.
3.
A mọ̀ Ọlọrun li àbo ninu ãfin rẹ̀.
4.
Sa wò o, awọn ọba pejọ pọ̀, nwọn jumọ nkọja lọ.
5.
Nwọn ri i, bẹ̃li ẹnu yà wọn; a yọ wọn lẹnu, nwọn yara lọ.
6.
Ẹ̀ru bà wọn nibẹ, ati irora bi obinrin ti nrọbi.
7.
Iwọ fi ẹfufu ila-õrun fọ́ ọkọ Tarṣiṣi.
8.
Bi awa ti gbọ́, bẹ̃li awa ri ni ilu Oluwa awọn ọmọ-ogun, ni ilu Ọlọrun wa: Ọlọrun yio gbé e kalẹ lailai.
9.
Awa ti nrò ti iṣeun-ifẹ rẹ, Ọlọrun, li arin tempili rẹ.
10.
Ọlọrun, gẹgẹ bi orukọ rẹ, bẹ̃ni iyìn rẹ de opin aiye: ọwọ ọtún rẹ kún fun ododo.
11.
Ki òke Sioni ki o yọ̀, ki inu awọn ọmọbinrin Juda ki o dùn, nitori idajọ rẹ.
12.
Rìn Sioni kiri, ki o si yi i ka: kà ile-iṣọ rẹ̀.
13.
Kiyesi odi rẹ̀, kiyesi ãfin rẹ̀ wọnni; ki ẹnyin le ma wi fun iran atẹle nyin.
14.
Nitori Ọlọrun yi Ọlọrun wa ni lai ati lailai: on ni yio ma ṣe amọna wa titi ikú.