1.
ỌLỌRUN gbà mi nipa orukọ rẹ, si ṣe idajọ mi nipa agbara rẹ.
2.
Gbọ́ adura mi, Ọlọrun; fi eti si ọ̀rọ ẹnu mi.
3.
Nitoriti awọn alejò dide si mi, awọn aninilara si nwá ọkàn mi: nwọn kò kà Ọlọrun si li oju wọn.
4.
Kiyesi i, Ọlọrun li oluranlọwọ mi: Oluwa wà pẹlu awọn ti o gbé ọkàn mi duro.
5.
Yio si fi ibi san a fun awọn ọta mi: ke wọn kuro ninu otitọ rẹ.
6.
Emi o rubọ atinuwa si ọ: Oluwa, emi o yìn orukọ rẹ; nitoriti o dara.
7.
Nitori o ti yọ mi kuro ninu iṣẹ́ gbogbo: oju mi si ri ifẹ rẹ̀ lara awọn ọta mi.