1.
NI Juda li a gbe mọ̀ Ọlọrun: orukọ rẹ̀ si pọ̀ ni Israeli.
2.
Ni Salemu pẹlu li agọ rẹ̀ wà, ati ibujoko rẹ̀ ni Sioni.
3.
Nibẹ li o gbe ṣẹ́ ọfà, ọrun, apata, ati idà, ati ogun na.
4.
Iwọ li ogo ati ọlá jù òke-nla ikogun wọnni lọ.
5.
A kó awọn alaiya lile ni ikogun, nwọn ti sùn orun wọn, gbogbo ọkunrin alagbara kò si ri ọwọ wọn.
6.
Nipa ibawi rẹ, Ọlọrun Jakobu, ati kẹkẹ́-ogun ati ẹṣin sun orun asunkú.
7.
Iwọ, ani iwọ li o ni ìbẹru: ati tani yio le duro niwaju rẹ, nigbati iwọ ba binu lẹ̃kan?
8.
Iwọ mu idajọ di gbigbọ́ lati ọrun wá: ilẹ aiye bẹ̀ru o si duro jẹ.
9.
Nigbati Ọlọrun dide si idajọ, lati gbà gbogbo ọlọkan-tutu aiye là.
10.
Nitõtọ ibinu enia yio yìn ọ: nigbati iwọ ba fi ibinu iyokù di ara rẹ li amure.
11.
Ẹ ṣe ileri ifẹ, ki ẹ si san a fun Oluwa, Ọlọrun nyin: jẹ ki gbogbo awọn ti o yi i ka ki o mu ẹ̀bun wá fun ẹniti a ba ma bẹ̀ru.
12.
On o ke ẹmi awọn ọmọ alade kuro: on si di ẹ̀ru si awọn ọba aiye.