1.
ỌLỌRUN duro ninu ijọ awọn alagbara; o nṣe idajọ ninu awọn ọlọrun.
2.
Ẹnyin o ti ṣe idajọ aiṣõtọ pẹ to, ti ẹ o si ma ṣe ojuṣaju awọn enia buburu?
3.
Ṣe idajọ talaka, ati ti alaini-baba: ṣe otitọ si awọn olupọnju ati alaini.
4.
Gbà talaka ati alaini: yọ wọn li ọwọ awọn enia buburu.
5.
Nwọn kò mọ̀, bẹ̃ni nwọn kò fẹ ki oye ki o ye wọn; nwọn nrìn li òkunkun; gbogbo ipilẹ aiye yẹ̀ ni ipò wọn.
6.
Emi ti wipe, ọlọrun li ẹnyin; awọn ọmọ Ọga-ogo si ni gbogbo nyin.
7.
Ṣugbọn ẹnyin o kú bi enia, ẹnyin o si ṣubu bi ọkan ninu awọn ọmọ-alade.
8.
Ọlọrun, dide, ṣe idajọ aiye: nitori iwọ ni yio ni orilẹ-ède gbogbo.