1.
MAṢE dakẹ, Ọlọrun: máṣe pa ẹnu rẹ mọ́, ki o má si ṣe duro jẹ, Ọlọrun.
2.
Sa wò o, awọn ọta rẹ nrọkẹ̀kẹ: awọn ti o korira rẹ ti gbé ori soke.
3.
Nwọn ti gbimọ̀ arekereke si awọn enia rẹ, nwọn si ti gbèro si awọn ẹni-ìkọ̀kọ̀ rẹ.
4.
Nwọn ti wipe, Ẹ wá, ẹ jẹ ki a ke wọn kuro lati má wà li orilẹ-ède; ki orukọ Israeli ki o máṣe si ni iranti mọ́.
5.
Nitoriti nwọn ti gbimọ̀ pọ̀ ṣọkan: nwọn ti dimọlu si ọ.
6.
Agọ Edomu, ati ti awọn ọmọ Iṣmaeli; ti Moabu, ati awọn ọmọ Hagari.
7.
Gebali, ati Ammoni, ati Amaleki: awọn ara Filistia pẹlu awọn ara Tire;
8.
Assuri pẹlu dapọ̀ mọ wọn: nwọn ràn awọn ọmọ Lotu lọwọ.
9.
Ṣe wọn bi o ti ṣe awọn ara Midiani; bi Sisera, bi Jabini, li odò Kiṣoni.
10.
Ẹniti o ṣegbe ni Endori: nwọn di àtan fun ilẹ.
11.
Ṣe awọn ọlọla wọn bi Orebu ati bi Sebu: ani, gbogbo awọn ọmọ-alade wọn bi Seba ati Salmuna.
12.
Awọn ti o wipe, Ẹ jẹ ki a gbà ibugbe Ọlọrun wọnni fun ara wa ni ini.
13.
Ọlọrun mi, ṣe wọn bi ãjà; bi akeku koriko niwaju afẹfẹ.
14.
Bi iná ti ijo igbo, ati bi ọwọ́ iná ti imu òke-nla gbiná;
15.
Bẹ̃ni ki o fi ẹ̀fufu rẹ ṣe inunibini si wọn, ki o si fi ìji rẹ dẹrubà wọn.
16.
Fi ìtiju kún wọn li oju: ki nwọn o le ma ṣe afẹri orukọ rẹ, Oluwa.
17.
Ki nwọn ki o dãmu ki a si pọ́n wọn loju lailai; nitõtọ, ki a dojutì wọn, ki nwọn ki o ṣegbé.
18.
Ki awọn enia ki o le mọ̀ pe iwọ, orukọ ẹni-kanṣoṣo ti ijẹ Jehofah, iwọ li Ọga-ogo lori aiye gbogbo.