1.
OLUWA jọba, ọla-nla li o wọ li aṣọ; agbara ni Oluwa wọ̀ li aṣọ, o fi di ara rẹ̀ li amure: o si fi idi aiye mulẹ, ti kì yio fi le yi.
2.
Lati igba atijọ li a ti fi idi itẹ́ rẹ kalẹ, ati aiye-raiye ni Iwọ.
3.
Iṣan-omi gbé ohùn wọn soke, Oluwa, iṣan-omi gbé ohùn wọn soke; iṣan-omi gbé riru omi wọn soke.
4.
Oluwa li ologo, o li ogo jù ariwo omi pupọ lọ, jù riru omi nla, ani jù agbara riru omi okun lọ.
5.
Otitọ li ẹri rẹ: ìwa-mimọ́ li o yẹ ile rẹ lailai, Oluwa.