1.
Ẹ kọrin titun si Oluwa: ẹ kọrin si Oluwa gbogbo aiye.
2.
Ẹ kọrin si Oluwa, fi ibukún fun orukọ rẹ̀; ẹ ma fi igbala rẹ̀ hàn lati ọjọ de ọjọ.
3.
Sọ̀rọ ogo rẹ̀ lãrin awọn keferi, ati iṣẹ iyanu rẹ̀ lãrin gbogbo enia.
4.
Nitori ti Oluwa tobi, o si ni iyìn pupọ̀pupọ̀: on li o ni ìbẹru jù gbogbo oriṣa lọ.
5.
Nitori pe gbogbo oriṣa orilẹ-ède asan ni nwọn: ṣugbọn Oluwa li o da ọrun.
6.
Ọlá ati ọla-nla li o wà niwaju rẹ̀: ipa ati ẹwà mbẹ ninu ibi mimọ́ rẹ̀.
7.
Ẹ fi fun Oluwa, ẹnyin ibatan enia, ẹ fi ogo ati ipá fun Oluwa.
8.
Ẹ fi ogo fun orukọ Oluwa: mu ọrẹ wá, ki ẹ si wá si agbala rẹ̀.
9.
Ẹ ma sìn Oluwa ninu ẹwà ìwa-mimọ́: ẹ wariri niwaju rẹ̀, gbogbo aiye.
10.
Ẹ wi lãrin awọn keferi pe, Oluwa jọba: nitõtọ a o fi idi aiye mulẹ ti kì yio le yẹ̀: on o fi ododo ṣe idajọ enia.
11.
Jẹ ki ọrun ki o yọ̀, jẹ ki inu aiye ki o dùn; jẹ ki okun ki o ma ho pẹlu ikún rẹ̀.
12.
Jẹ ki oko ki o kún fun ayọ̀, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu rẹ̀: nigbana ni gbogbo igi igbo yio ma yọ̀.
13.
Niwaju Oluwa: nitoriti mbọwa, nitori ti mbọwa ṣe idajọ aiye: yio fi ododo ṣe idajọ aiye, ati ti enia ni yio fi otitọ rẹ̀ ṣe.