1.
ỌLỌGBỌ́N ọmọ gbà ẹkọ́ baba rẹ̀; ṣugbọn ẹlẹgàn kò gbọ́ ibawi.
2.
Enia yio jẹ rere nipa ère ẹnu rẹ̀; ṣugbọn ifẹ ọkàn awọn olurekọja ni ìwa-agbara.
3.
Ẹniti o pa ẹnu rẹ̀ mọ́, o pa ẹmi rẹ̀ mọ́; ṣugbọn ẹniti o ṣi ète rẹ̀ pupọ yio ni iparun.
4.
Ọkàn ọlẹ nfẹ, kò si ri nkan; ṣugbọn ọkàn awọn alãpọn li a o mu sanra.
5.
Olododo korira ẹ̀tan; ṣugbọn enia buburu mu ni hu ìwa irira on itiju.
6.
Ododo pa aduro-ṣinṣin li ọ̀na mọ́; ṣugbọn ìwa-buburu ni imuni ṣubu sinu ẹ̀ṣẹ.
7.
Ẹnikan wà ti o nfi ara rẹ̀ ṣe ọlọrọ̀, ṣugbọn kò ni nkan; ẹnikan wà ti o nfi ara rẹ̀ ṣe talaka ṣugbọn o li ọrọ̀ pupọ.
8.
Irapada ẹmi enia li ọrọ̀ rẹ̀; ṣugbọn olupọnju kò kiyesi ibawi.
9.
Imọlẹ olododo nfi ayọ̀ jó; ṣugbọn fitila enia buburu li a o pa.
10.
Nipa kiki igberaga ni ìja ti iwá; ṣugbọn lọdọ awọn ti a fi ìmọ hàn li ọgbọ́n wà.
11.
Ọrọ̀ ti a fi ìwa-asan ni yio fàsẹhin; ṣugbọn ẹniti o fi iṣẹ-ọwọ kojọ ni yio ma pọ̀ si i.
12.
Ireti pipẹ mu ọkàn ṣàisan; ṣugbọn nigbati ifẹ ba de, igi ìye ni.
13.
Ẹnikan ti o ba gàn ọ̀rọ na li a o parun: ṣugbọn ẹniti o bẹ̀ru ofin na, li a o san pada fun.
14.
Ofin ọlọgbọ́n li orisun ìye, lati kuro ninu okùn ikú.
15.
Oye rere fi ojurere fun ni; ṣugbọn ọ̀na awọn olurekọja ṣoro.
16.
Gbogbo amoye enia ni nfi ìmọ ṣiṣẹ; ṣugbọn aṣiwere tan were rẹ̀ kalẹ.
17.
Oniṣẹ buburu bọ́ sinu ipọnju; ṣugbọn olõtọ ikọ̀ mu ilera wá.
18.
Oṣi ati itiju ni fun ẹniti o kọ̀ ẹkọ́; ṣugbọn ẹniti o ba fetisi ibawi li a o bu ọlá fun.
19.
Ifẹ ti a muṣẹ dùnmọ ọkàn; ṣugbọn irira ni fun aṣiwere lati kuro ninu ibi.
20.
Ẹniti o mba ọlọgbọ́n rìn yio gbọ́n; ṣugbọn ẹgbẹ awọn aṣiwere ni yio ṣegbe.
21.
Ibi nlepa awọn ẹlẹṣẹ̀; ṣugbọn fun awọn olododo, rere li a o ma fi san a.
22.
Enia rere fi ogún silẹ fun awọn ọmọ ọmọ rẹ̀; ṣugbọn ọrọ̀ ẹlẹṣẹ̀ li a tò jọ fun olododo,
23.
Onjẹ pupọ li o wà ni ilẹ titun awọn talaka; ṣugbọn awọn kan wà ti a nparun nitori aini idajọ;
24.
Ẹniti o ba fà ọwọ paṣan sẹhin, o korira ọmọ rẹ̀; ṣugbọn ẹniti o fẹ ẹ a ma tète nà a.
25.
Olododo jẹ to itẹrun ọkàn rẹ̀; ṣugbọn inu awọn enia buburu ni yio ṣe alaini.