1.MÁṢE leri ara rẹ niti ọjọ ọla, nitoriti iwọ kò mọ̀ ohun ti ọjọ kan yio hù jade.
2.Jẹ ki ẹlomiran ki o yìn ọ, ki o máṣe ẹnu ara rẹ; alejo, ki o má si ṣe ète ara rẹ.
3.Okuta wuwo, yanrin si wuwo, ṣugbọn ibinu aṣiwère, o wuwo jù mejeji lọ.
4.Ibinu ni ìka, irunu si ni kikún-omi; ṣugbọn tani yio duro niwaju owú.
5.Ibawi nigbangba, o san jù ifẹ ti o farasin lọ.
6.Otitọ li ọgbẹ ọrẹ́: ṣugbọn ifẹnukonu ọta li ẹ̀tan.
7.Ọkàn ti o yó fi ẹsẹ tẹ afara-oyin; ṣugbọn ọkàn ti ebi npa, ohun kikoro gbogbo li o dùn.
8.Bi ẹiyẹ ti ima fò kiri lati inu itẹ́ rẹ̀, bẹ̃li enia ti o nrìn kiri jina si ipò rẹ̀.
9.Ororo ati turari mu ọkàn dùn: bẹ̃ni adùn ọrẹ ẹni nipa ìgbimọ atọkànwa.
10.Ọrẹ́ rẹ ati ọrẹ́ baba rẹ, máṣe kọ̀ silẹ, bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe lọ si ile arakunrin li ọjọ idãmu rẹ: nitoripe aladugbo ti o sunmọ ni, o san jù arakunrin ti o jina rere lọ.
11.Ọmọ mi, ki iwọ ki o gbọ́n, ki o si mu inu mi dùn; ki emi ki o le da ẹniti ngàn mi lohùn.
12.Amoye enia ri ibi tẹlẹ, o si pa ara rẹ̀ mọ́; ṣugbọn awọn òpe kọja a si jẹ wọn niya.
13.Gbà aṣọ rẹ̀ nitoriti o ṣe onigbọwọ alejo, si gbà ohun ẹri lọwọ rẹ̀ fun ajeji obinrin.
14.Ẹniti o ba ndide ni kutukutu ti o nfi ohùn rara kí ọrẹ́ rẹ̀, egún li a o kà a si fun u.
15.Ọṣọrọ-òjo li ọjọ òjo, ati onija obinrin, bakanna ni.
16.Ẹnikẹni ti o pa a mọ́, o pa ẹfũfu mọ́, ororo ọwọ-ọtún rẹ̀ yio si fihàn.
17.Irin a ma pọn irin: bẹ̃li ọkunrin ipọn oju ọrẹ́ rẹ̀.
18.Ẹnikẹni ti o tọju igi-ọpọtọ yio jẹ eso rẹ̀; bẹ̃li ẹniti o duro tì oluwa rẹ̀ li a o buyì fun.
19.Bi oju ti ikò oju li omi, bẹ̃li aiya enia si enia.
20.Ipò-okú ati iparun kì ikún, bẹ̃ni kì isu oju enia.
21.Bi koro fun fadaka, ati ileru fun wura, bẹ̃li enia si iyìn rẹ̀.
22.Bi iwọ tilẹ fi ọmọri-odó gún aṣiwère ninu odo larin alikama, wère rẹ̀ kì yio fi i silẹ.
23.Iwọ ma ṣaniyan ati mọ̀ ìwa agbo-ẹran rẹ, ki iwọ ki o si bojuto awọn ọwọ-ẹran rẹ.
24.Nitoripe ọrọ̀ ki iwà titi lai: ade a ha si ma wà de irandiran?
25.Koriko yọ, ati ọmunú koriko fi ara han, ati ewebẹ̀ awọn òke kojọ pọ̀.
26.Awọn ọdọ-agutan ni fun aṣọ rẹ, awọn obukọ si ni iye-owo oko.
27.Iwọ o si ni wàra ewurẹ to fun onjẹ rẹ, fun onjẹ awọn ara ile rẹ, ati fun onjẹ awọn iranṣẹ-birin rẹ.