1.GBỌ ti emi, ẹnyin ti ntẹle ododo, ẹnyin ti nwá Oluwa; wò apáta nì ninu eyiti a ti gbẹ́ nyin, ati ihò kòto nì nibiti a gbe ti wà nyin.
2.Ẹ wò Abrahamu baba nyin, ati Sara ti o bi nyin; nitori on nikan ni mo pè, mo si sure fun u, mo si mu u pọ̀ si i.
3.Nitori Oluwa yio tù Sioni ninu; yio tú gbogbo ibi ofo rẹ̀ ninu; yio si ṣe aginju rẹ̀ bi Edeni, ati aṣálẹ rẹ̀ bi ọgbà Oluwa, ayọ̀ ati inudidùn li a o ri ninu rẹ̀, idupẹ, ati ohùn orin.
4.Tẹtilelẹ si mi, ẹnyin enia mi; si fi eti si mi, iwọ orilẹ-ède mi: nitori ofin kan yio ti ọdọ mi jade lọ, emi o si gbe idajọ mi kalẹ fun imọlẹ awọn enia.
5.Ododo mi wà nitosí; igbala mi ti jade lọ, apá mi yio si ṣe idajọ awọn enia; awọn erekùṣu yio duro dè mi, apá mi ni nwọn o si gbẹkẹle.
6.Ẹ gbé ojú nyin soke si awọn ọrun, ki ẹ si wò aiye nisalẹ: nitori awọn ọrun yio fẹ́ lọ bi ẹ̃fin, aiye o si di ogbó bi ẹwù, awọn ti ngbe inu rẹ̀ yio si kú bakanna: ṣugbọn igbala mi o wà titi lai, ododo mi kì yio si parẹ́.
7.Gbọ́ ti emi, ẹnyin ti o mọ̀ ododo, enia ninu aiya ẹniti ofin mi mbẹ; ẹ máṣe bẹ̀ru ẹgàn awọn enia, ẹ má si ṣe foyà ẹsín wọn.
8.Nitori kòkoro yio jẹ wọn bi ẹ̀wu, idin yio si jẹ wọn bi irun agutan: ṣugbọn ododo mi yio wà titi lai, ati igbala mi lati iran de iran.
9.Ji, ji, gbe agbara wọ̀, Iwọ apa Oluwa; ji, bi li ọjọ igbãni, ni iran atijọ. Iwọ kọ́ ha ke Rahabu, ti o si ṣá Dragoni li ọgbẹ́?
10.Iwọ kọ́ ha gbẹ okun, omi ibu nla wọnni? ti o ti sọ ibú okun di ọ̀na fun awọn ẹni ìrapada lati gbà kọja?
11.Nitorina awọn ẹni-ìrapada Oluwa yio pada, nwọn o si wá si Sioni ti awọn ti orin; ayọ̀ ainipẹkun yio si wà li ori wọn: nwọn o ri inudidùn ati ayọ̀ gbà; ikãnu ati ọ̀fọ yio fò lọ.
12.Emi, ani emi ni ẹniti ntù nyin ninu: tani iwọ, ti iwọ o fi bẹ̀ru enia ti yio kú, ati ọmọ enia ti a ṣe bi koriko.
13.Ti iwọ si gbagbe Oluwa Elẹda rẹ ti o ti nà awọn ọrun, ti o si ti fi ipilẹ aiye sọlẹ; ti iwọ si ti mbẹ̀ru nigbagbogbo lojojumọ nitori irúnu aninilara nì, bi ẹnipe o ti mura lati panirun? nibo ni irúnu aninilara na ha gbe wà?
14.Ondè ti a ti ṣí nipo yara ki a ba le tú u silẹ, ati ki o má ba kú sinu ihò, tabi ki onjẹ rẹ̀ má ba tán.
15.Ṣugbọn emi Oluwa Ọlọrun rẹ ti o pin okun ni iyà, eyi ti ìgbi rẹ̀ nhó; Oluwa awọn ọmọ-ogun ni orukọ rẹ̀.
16.Emi si ti fi ọ̀rọ mi si ẹnu rẹ, mo si ti bò ọ mọlẹ ni ojiji ọwọ́ mi, ki emi ki o le gbìn awọn ọrun, ki emi si le fi ipilẹ aiye sọlẹ, ati ki emi le wi fun Sioni pe, Iwọ ni enia mi.
17.Ji, ji, dide duro, iwọ Jerusalemu, ti o ti mu li ọwọ́ Oluwa ago irúnu rẹ̀; iwọ ti mu gẹ̀dẹgẹ́dẹ̀ ago ìwarìri, iwọ si fọ́n wọn jade.
18.Kò si ẹnikan ninu gbogbo awọn ọmọ ọkunrin ti o bí lati tọ́ ọ; bẹ̃ni kò si ẹniti o fà a lọwọ, ninu gbogbo awọn ọmọ ọkunrin ti on tọ́ dàgba.
19.Ohun meji wọnyi li o débá ọ: tani o kãnu fun ọ? idahoro, on iparun, ati ìyan, on idà: nipa tani emi o tù ọ ninu?
20.Awọn ọmọ rẹ ọkunrin ti dáku, nwọn dubulẹ ni gbogbo ikorita, bi ẹfọ̀n ninu àwọn: nwọn kún fun ìrúnu Oluwa, ibawi Ọlọrun rẹ.
21.Nitorina gbọ́ eyi na, iwọ ẹniti a pọ́n loju, ti o si mu amuyo, ṣugbọn kì iṣe nipa ọti-waini:
22.Bayi ni Oluwa rẹ Jehofa wi, ati Ọlọrun rẹ ti ngbèja enia rẹ̀, Kiyesi i, emi ti gbà ago ìwárìri kuro lọwọ rẹ, gẹ̀dẹgẹ́dẹ̀ ago irúnu mi; iwọ kì yio si mu u mọ.
23.Ṣugbọn emi o fi i si ọwọ́ awọn ti o pọ́n ọ loju; ti nwọn ti wi fun ọkàn rẹ pe, Wólẹ, ki a ba le rekọja: iwọ si ti tẹ́ ara rẹ silẹ bi ilẹ, ati bi ita, fun awọn ti o rekọja.