1.Ọ̀RỌ Amosi, ẹniti o wà ninu awọn darandaran Tekoa, ti o ri niti Israeli li ọjọ ọba Ussiah ọba Juda, ati li ọjọ Jeroboamu ọmọ Joaṣi ọba Israeli, ọdun meji ṣãju isẹ̀lẹ nì.
2.O si wipe, Oluwa yio bu jade lati Sioni wá, yio si fọ̀ ohùn rẹ̀ lati Jerusalemu wá; ibùgbe awọn olùṣọ-agùtan yio si ṣọ̀fọ, oke Karmeli yio si rọ.
3.Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Damasku, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn ti fi ohunèlo irin ipakà pa Gileadi:
4.Ṣugbọn emi o rán iná kan si ile Hasaeli, ti yio jo ãfin Benhadadi wọnni run.
5.Emi o ṣẹ ọpá idabu Damasku pẹlu, emi o si ke ará pẹ̀tẹlẹ Afeni kuro, ati ẹniti o dì ọpá alade nì mu kuro ni ile Edeni: awọn enia Siria yio si lọ si igbèkun si Kiri, ni Oluwa wi.
6.Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Gasa, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn ti kó gbogbo igbèkun ni igbèkun lọ, lati fi wọn le Edomu lọwọ.
7.Ṣugbọn emi o rán iná kan sara odi Gasa, ti yio jo ãfin rẹ̀ wọnni run:
8.Emi o si ke ara Aṣdodi kuro, ati ẹniti o di ọpá alade mu kuro ni Aṣkeloni, emi o si yi ọwọ́ mi si Ekroni; iyokù ninu awọn ara Filistia yio ṣegbe, li Oluwa Ọlọrun wi.
9.Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Tire, ati nitori mẹrin: emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn fi gbogbo igbèkun le Edomu lọwọ, nwọn kò si ranti majẹmu arakunrin.
10.Ṣugbọn emi o rán iná kan sara odi Tire, ti yio jo ãfin rẹ̀ wọnni run.
11.Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Edomu, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori o fi idà lepa arakunrin rẹ̀, o si gbe gbogbo ãnu sọnù; ibinu rẹ̀ si nfaniya titi, o si pa ibinu rẹ̀ mọ titi lai.
12.Ṣugbọn emi o rán iná kan si Temani, ti yio jó afin Bosra wọnni run.
13.Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti awọn ọmọ Ammoni, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn ti là inu awọn aboyun Gileadi, ki nwọn le ba mu agbègbe wọn tobi:
14.Ṣugbọn emi o da iná kan ninu odi Rabba, yio si jó ãfin rẹ̀ wọnni run, pẹlu iho ayọ̀ li ọjọ ogun, pẹlu ijì li ọjọ ãjà:
15.Ọba wọn o si lọ si igbèkun, on ati awọn ọmọ-alade rẹ̀ pọ̀, li Oluwa wi.