1.OSI ṣe li ọjọ́ na ti Mose gbé agọ́ na ró tán, ti o si ta oróro si i ti o si yà a simimọ́, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati pẹpẹ na ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ti o si ta oróro si wọn, ti o si yà wọn simimọ́;
2.Ni awọn ijoye Israeli, awọn olori ile baba wọn, awọn olori ẹ̀ya wọnni, ti iṣe olori awọn ti a kà, mú ọrẹ wá:
3.Nwọn si mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá siwaju OLUWA, kẹkẹ́-ẹrù mẹfa ti a bò, ati akọmalu mejila; kẹkẹ́-ẹrù kan fun ijoye meji, ati akọmalu kan fun ọkọkan: nwọn si mú wọn wá siwaju agọ́ ajọ.
4.OLUWA si sọ fun Mose pe,
5.Gbà a lọwọ wọn, ki nwọn ki o le jẹ́ ati fi ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ; ki iwọ ki o si fi wọn fun awọn ọmọ Lefi, fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin rẹ̀.
6.Mose si gbà kẹkẹ́-ẹrù wọnni, ati akọmalu, o si fi wọn fun awọn ọmọ Lefi.
7.Kẹkẹ́-ẹrù meji ati akọmalu mẹrin, li o fi fun awọn ọmọ Gerṣoni, gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin wọn:
8.Ati kẹkẹ́-ẹrù mẹrin ati akọmalu mẹjọ li o fi fun awọn ọmọ Merari, gẹgẹ bi iṣẹ-ìsin wọn, li ọwọ́ Itamari ọmọ Aaroni alufa.
9.Ṣugbọn kò fi fun awọn ọmọ Kohati: nitoripe iṣẹ-ìsin ibi-mimọ́ ni ti wọn; li ohun ti nwọn o ma fi ejika rù.
10.Awọn olori si mú ọrẹ wá fun ìyasimimọ́ pẹpẹ li ọjọ́ ti a ta oróro si i, ani awọn olori mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá siwaju pẹpẹ na.
11.OLUWA si wi fun Mose pe, Ki nwọn ki o ma mú ọrẹ-ẹbọ wọn wá, olukuluku olori li ọjọ́ tirẹ̀ fun ìyasimimọ̀ pẹpẹ.
12.Ẹniti o si mú ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ wá li ọjọ́ kini ni Naṣoni ọmọ Amminadabu, ti ẹ̀ya Juda.
13.Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ si jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ;
14.Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;
15.Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun;
16.Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ;
17.Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Naṣoni ọmọ Amminadabu.
18.Li ọjọ́ keji ni Netaneeli ọmọ Suari, olori ti Issakari mú ọrẹ wá:
19.On múwa fun ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ:
20.Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;
21.Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun;
22.Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ;
23.Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Netaneeli ọmọ Suari.
24.Li ọjọ́ kẹta Eliabu ọmọ Heloni, olori awọn ọmọ Sebuluni:
25.Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ;
26.Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;
27.Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun;
28.Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ;
29.Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Eliabu ọmọ Heloni.
30.Li ọjọ́ kẹrin Elisuri ọmọ Ṣedeuri, olori awọn ọmọ Reubeni;
31.Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ̀ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò fun ẹbọ ohunjijẹ;
32.Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;
33.Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun;
34.Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ;
35.Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Elisuri ọmọ Ṣedeuri.
36.Li ọjọ́ karun Ṣelumieli ọmọ Suriṣuddai, olori awọn ọmọ Simeoni:
37.Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò fun ẹbọ ohunjijẹ;
38.Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;
39.Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun;
40.Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ;
41.Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ Ṣelumieli ọmọ Ṣuriṣaddai.
42.Li ọjọ́ kẹfa Eliasafu ọmọ Deueli, olori awọn ọmọ Gadi:
43.Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò fun ẹbọ ohunjijẹ;
44.Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;
45.Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun;
46.Akọ ewure kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ;
47.Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ Eliasafu ọmọ Deueli.
48.Li ọjọ́ keje Eliṣama ọmọ Ammihudu, olori awọn ọmọ Efraimu:
49.Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ;
50.Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;
51.Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun;
52.Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ;
53.Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ Eliṣama ọmọ Ammihudu.
54.Li ọjọ́ kẹjọ Gamalieli ọmọ Pedasuri, olori awọn ọmọ Manasse:
55.Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ;
56.Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;
57.Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun;
58.Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ;
59.Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Gamalieli ọmọ Pedasuri.
60.Li ọjọ́ kẹsan Abidani ọmọ Gideoni, olori awọn ọmọ Benjamini:
61.Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ;
62.Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;
63.Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun;
64.Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ;
65.Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Abidani ọmọ Gideoni.
66.Li ọjọ́ kẹwá ni Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai, olori awọn ọmọ Dani:
67.Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ìwọn ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ:
68.Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;
69.Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun;
70.Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ;
71.Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Ahieseri ọmọ Ammiṣaddai.
72.Li ọjọ́kọkanla Pagieli ọmọ Okrani, olori awọn ọmọ Aṣeri:
73.Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ́ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ìwọn ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ;
74.Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;
75.Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun;
76.Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ;
77.Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Pagieli ọmọ Okrani.
78.Li ọjọ́ kejila Ahira ọmọ Enani, olori awọn ọmọ Naftali:
79.Ọrẹ-ẹbọ tirẹ̀ jẹ̀ awopọkọ kan ti fadakà, ìwọn rẹ̀ jẹ́ ãdoje ṣekeli, awokòto kan ti fadakà ãdọrin ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; mejeji wọn kún fun iyẹfun daradara ti a fi oróro pò, fun ẹbọ ohunjijẹ;
80.Ṣibi kan ìwọn ṣekeli mẹwa wurà, o kún fun turari;
81.Ẹgbọrọ akọmalu kan, àgbo kan, akọ ọdọ-agutan kan ọlọdún kan, fun ẹbọ sisun;
82.Akọ ewurẹ kan fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ;
83.Ati fun ẹbọ ti ẹbọ alafia, akọmalu meji, àgbo marun, obukọ marun, akọ ọdọ-agutan marun ọlọdún kan: eyi li ọrẹ-ẹbọ ti Ahira ọmọ Enani.
84.Eyi ni ìyasimimọ́ pẹpẹ, li ọjọ́ ti a ta oróro si i, lati ọwọ́ awọn olori Israeli wá: awopọkọ fadakà mejila, awokòto fadakà mejila, ṣibi wurà mejila:
85.Awopọkọ fadakà kọkan jẹ́ ãdoje ṣekeli: awokòto kọkan jẹ́ ãdọrin: gbogbo ohun-èlo fadakà jẹ́ egbejila ṣekeli, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́;
86.Ṣibi wurà jẹ́ mejila, nwọn kún fun turari, ṣibi kọkan jẹ́ ṣekeli mẹwa, gẹgẹ bi ṣekeli ibi-mimọ́; gbogbo wurà agọ́ na jẹ́ ọgọfa ṣekeli.
87.Gbogbo akọmalu fun ẹbọ sisun jẹ́ ẹgbọrọ akọmalu mejila, àgbo mejila, akọ ọdọ-agutan ọlọdún kan mejila, pẹlu ẹbọ ohunjijẹ wọn: ati akọ ewurẹ fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ, mejila.
88.Ati gbogbo akọmalu fun ẹbọ ti ẹbọ alafia jẹ́ akọmalu mẹrinlelogun, àgbo ọgọta, obukọ ọgọta, akọ ọdọ-agutan ọlọdún kan ọgọta. Eyi ni ìyasimimọ́ pẹpẹ, lẹhin igbati a ta oróro si i.
89.Nigbati Mose si wọ̀ inu agọ́ ajọ lọ lati bá a (Ọlọrun) sọ̀rọ, nigbana li o gbọ́ ohùn ti nfọ̀ si i lati ori itẹ́-ãnu nì wá ti mbẹ lori apoti ẹrí, lati agbedemeji awọn kerubu meji nì wá: o si bá a sọ̀rọ.