1.
NITORINA ẹ duro ṣinṣin ninu omnira na eyi ti Kristi fi sọ wa di omnira, ki ẹ má si ṣe tún fi ọrùn bọ àjaga ẹrú mọ́.
🔗
📤
2.
Kiyesi i, emi Paulu li o wi fun nyin pe, bi a ba kọ nyin nila, Kristi ki yio li ère fun nyin li ohunkohun.
🔗
📤
3.
Mo si tún sọ fun olukuluku enia ti a kọ ni ila pe, o di ajigbese lati pa gbogbo ofin mọ́.
🔗
📤
4.
A ti yà nyin kuro lọdọ Kristi, ẹnyin ti nfẹ ki a da nyin lare nipa ofin; ẹ ti ṣubu kuro ninu ore-ọfẹ.
🔗
📤
5.
Nitori nipa Ẹmí awa nfi igbagbọ duro de ireti ododo.
🔗
📤
6.
Nitori ninu Kristi Jesu ikọla kò jẹ ohun kan, tabi aikọla; ṣugbọn igbagbọ́ ti nṣiṣẹ nipa ifẹ.
🔗
📤
7.
Ẹnyin ti nsáre daradara; tani ha dí nyin lọwọ ki ẹnyin ki o máṣe gba otitọ?
🔗
📤
8.
Iyipada yi kò ti ọdọ ẹniti o pè nyin wá.
🔗
📤
9.
Iwukara kiun ni imu gbogbo iyẹfun wu.
🔗
📤
10.
Mo ni igbẹkẹle si nyin ninu Oluwa pe, ẹnyin kì yio ni ero ohun miran; ṣugbọn ẹniti nyọ nyin lẹnu yio rù idajọ tirẹ̀, ẹnikẹni ti o wù ki o jẹ.
🔗
📤
11.
Ṣugbọn, ara, bi emi ba nwasu ikọla sibẹ, ehatiṣe ti a nṣe inunibini si mi sibẹ? njẹ ikọsẹ agbelebu ti kuro.
🔗
📤
12.
Emi iba fẹ ki awọn ti nyọ nyin lẹnu tilẹ ké ara wọn kuro.
🔗
📤
13.
Nitori a ti pè nyin si omnira, ará; kiki pe ki ẹ máṣe lò omnira nyin fun àye sipa ti ara, ṣugbọn ẹ mã fi ifẹ sìn ọmọnikeji nyin.
🔗
📤
14.
Nitoripe a kó gbogbo ofin já ninu ọ̀rọ kan, ani ninu eyi pe; Iwọ fẹ ọmọnikeji rẹ bi ara rẹ.
🔗
📤
15.
Ṣugbọn bi ẹnyin ba mbù ara nyin ṣán, ti ẹ si njẹ ara nyin run, ẹ kiyesara ki ẹ máṣe pa ara nyin run.
🔗
📤
16.
Njẹ mo ni, Ẹ ma rìn nipa ti Ẹmí, ẹnyin kì yio si mu ifẹkufẹ ti ara ṣẹ.
🔗
📤
17.
Nitoriti ara nṣe ifẹkufẹ lodi si Ẹmí, ati Ẹmí lodi si ara: awọn wọnyi si lodi si ara wọn; ki ẹ má ba le ṣe ohun ti ẹnyin nfẹ.
🔗
📤
18.
Ṣugbọn bi a ba nti ọwọ Ẹmí ṣamọna nyin, ẹnyin kò si labẹ ofin.
🔗
📤
19.
Njẹ awọn iṣẹ ti ara farahàn, ti iṣe wọnyi; panṣaga, àgbere, ìwa-ẽri, wọ̀bia,
🔗
📤
20.
Ibọriṣa, oṣó, irira, ìja, ilara, ibinu, asọ, ìṣọtẹ, adamọ̀,
🔗
📤
21.
Arankàn, ipania, imutipara, iréde-oru, ati iru wọnni: awọn ohun ti mo nwi fun nyin tẹlẹ, gẹgẹ bi mo ti wi fun nyin tẹlẹ rí pe, awọn ti nṣe nkan bawọnni kì yio jogún ijọba Ọlọrun.
🔗
📤
22.
Ṣugbọn eso ti Ẹmí ni ifẹ, ayọ̀, alafia, ipamọra, ìwa pẹlẹ, iṣore, igbagbọ́,
🔗
📤
23.
Ìwa tutù, ati ikora-ẹni-nijanu: ofin kan kò lodi si iru wọnni.
🔗
📤
24.
Awọn ti iṣe ti Kristi Jesu ti kàn ara mọ agbelebu ti on ti ifẹ ati ifẹkufẹ rẹ̀.
🔗
📤
25.
Bi awa ba wà lãye sipa ti Ẹmí, ẹ jẹ ki a si mã rìn nipa ti Ẹmí.
🔗
📤
26.
Ẹ máṣe jẹ ki a mã ṣogo-asan, ki a má mu ọmọnikeji wa binu, ki a má ṣe ilara ọmọnikeji wa.
🔗
📤